Postado por Daniele em 31/12/2006 18:52
Oyá - Minha Vida
Oyà A To Iwo Efòn Gbé.
Oyà Olókò Àra.
Obìnrin Ogun,
Obìnrin Ode.
Oya Òrírì Arójú Bá Oko Kú.
.
Iru Èniyàn Wo Ni Oyà Yí N Se, Se?
Ibi Oya Wà, Ló Gbiná.
Obìnrin Wóò Bi Eni Fó Igbá.
Oyà tí awon òtá rí,
Tí Won Torí Rè Da Igbá Nù Sì Igbó.
Héèpà Héè, Oya ò!
Erù Re Nikan Ni Mo Nbà O.
Aféfé Ikú.
Obìnrin Ogun, Ti Ná Ibon Rè Ní À Ki Kún
Oyà ò, Oyà Tótó Hun!
Oyà, A P’Agbá, P’Àwo Mó Ni Kíákíá,
Kíákíá, Wéré Wéré L’ Oyà Nse Ti È
A Rìn Dengbere Bíi Fúlàní.
O Titi Tí Nfi Gbogbo Ará Rìn Bí Esin
Héèpà, Oya Olómo Mesan, Ibá Re Ò!